ÀBẸ̀WÒ ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ ÈDÈ YORÙBÁ LÁTI ORÍ-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ SÍ YORÙBÁ WORLD CENTRE.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí tún ní àǹfààní láti rí àwọn nǹkan àtijọ́, àwòrán àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé tí ó wúlò fún iṣẹ́ ìwádìí àti ìmọ̀ nípa ìtàn, àṣà, èdè àti ìṣe àwa ọmọ Odùaà.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ èdè yoruba láti Fásitì oríṣiríṣi lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní wọ́n ṣàbẹ̀wò sì Yorùbá World Centre tí ó wà nínú ọgbà Fásitì Ìbàdàn.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí ní àǹfààní láti gbọ́ orin àtijó láti ẹnu Àyànlolá Tìjání gbajúmọ̀ asun rárà /onírárà.