There’s something about Ọ̀fà people that I love so much. No matter how successful they become, their ancestral home remains deeply important to them.
I’ve seen the eyes of an Ọ̀fà man light up the moment he realizes the person he’s speaking with is also from Ọ̀fà. The camaraderie is out of this world.
I’ve always known Ìjẹ̀bú, Ìbàdàn, Ẹ̀gbá, and Lagos people to carry a special pride in their place of origin, but I think what Ọ̀fà people have is truly unique.
They also seem to love one another deeply. I loveeeeet😊
Ìyẹ̀rú Ọ̀kín Ọlọ́fà ló lỌ̀fà
Ọlálọmí, ọlọ́mọ ló lọmọ
Ọlálọmí ọmọ abíṣu jóókọ
Ọlálọmí ọmọ abiṣu dá rangbọndan kánú oko.
Alukósó ọlọ́fà egbèjé
Alubẹ̀m̀bẹ̀ ọlọ́fà ẹgbẹ̀fà
Alukínrínjìngbín ọlọ́fà ẹgbẹ̀rindínlógún
Ọ̀fà ò màká, ẹrú ẹ̀ ló mọ̀ọ́ká.
Àkẹ́bàjẹ́ ló ba ọmọ Ọlálọmí je
Tó fi jẹ́ kí ẹrú ó mọ ilá má ju ọmọ lọ
Ọmọ bùúure, làáare, ọ̀kan ò gbọdọ̀ jùkan. Bọ́kan bá jùkan, ogun ní ń dá sílé baba tó bí wọn lọ́mọ.
Ọmọ ìjà kan, ìjà kàn, tó ṣẹlẹ̀ lỌ́fà lọ́jọ́sí
Ó ṣojúu poro nínú okò
Ó ṣojú ebè láàlà
Ó ṣojú agbélẹ̀yaràrá
Ó ṣojúu lápàkálẹ̀
Ó ṣojúu lágùn-nana kànrun
Ìbá ṣojú olóko, ìbá là wọ́n.
.....