ISIKIẸLI 37:5 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun egungun wọnyi; Kiyesi i, emi o mu ki ẽmi wọ̀ inu nyin, ẹnyin o si yè: Thus saith the Lord GOD unto these bones; Behold, I will cause breath to enter into you, and ye shall live:
ORIN DAFIDI 23:5 Iwọ tẹ́ tabili onjẹ silẹ niwaju mi li oju awọn ọta mi; iwọ dà ororo si mi li ori; ago mi si kún akúnwọsilẹ. Thou preparest a table before me in the presence of mine enemies: thou anointest my head with oil; my cup runneth over.
JEREMAYA 30:17 For I will restore health unto thee, and I will heal thee of thy wounds, saith the LORD; because they called thee an Outcast, saying, This is Zion, whom no man seeketh after.
NỌMBA 23:23 Surely there is no enchantment against Jacob, neither is there any divination against Israel: according to this time it shall be said of Jacob and of Israel, What hath God wrought!
ÌFIHÀN 12:11 Nwọn si ṣẹgun rẹ̀ nitori ẹ̀jẹ Ọdọ-Agutan na, ati nitori ọ̀rọ ẹrí wọn, nwọn kò si fẹran ẹmi wọn ani titi de ikú. And they overcame him by the blood of the Lamb, and by the word of their testimony; and they loved not their lives unto the death.
HEBERU 6:10 For God is not unrighteous to forget your work and labour of love, which ye have shewed toward his name, in that ye have ministered to the saints, and do minister.
ORIN DAFIDI 31:1 OLUWA, iwọ ni mo gbẹkẹ mi le: máṣe jẹ ki oju ki o tì mi: gbà mi ninu ododo rẹ. (To the chief Musician, A Psalm of David.) In thee, O LORD, do I put my trust; let me never be ashamed: deliver me in thy righteousness.
ORIN DAFIDI 29:3 Ohùn Oluwa mbẹ lori omi pupọ̀: Ọlọrun ogo nsán ãrá: Oluwa mbẹ lori omi pupọ̀. The voice of the LORD is upon the waters: the God of glory thundereth: the LORD is upon many waters.
ORIN DAFIDI 34:10 Awọn ọmọ kiniun a ma ṣe alaini, ebi a si ma pa wọn: ṣugbọn awọn ti nwá Oluwa, kì yio ṣe alaini ohun ti o dara. The young lions do lack, and suffer hunger: but they that seek the LORD shall not want any good thing.
KỌRINTI KINNI 13:1 BI mo tilẹ nfọ oniruru ede ati ti angẹli, ti emi kò si ni ifẹ, emi dabi idẹ ti ndún, tabi bi kimbali olohùn goro. Though I speak with the tongues of men and of angels, and have not charity, I am become as sounding brass, or a tinkling cymbal.
NỌMBA 6:24 Ki OLUWA ki o busi i fun ọ, ki o si pa ọ mọ́: The LORD bless thee, and keep thee:
NỌMBA 6:25 Ki OLUWA ki o mu oju rẹ̀ mọlẹ si ọ lara, ki o si ṣãnu fun ọ: The LORD make his face shine upon thee, and be gracious unto thee:
AISAYA 54:15 Kiye si i, ni kikojọ nwọn o kó ara wọn jọ, ṣugbọn ki iṣe nipasẹ mi; ẹnikẹni ti o ba ditẹ si ọ yio ṣubu nitori rẹ. Behold, they shall surely gather together, but not by me: whosoever shall gather together against thee shall fall for thy sake.
ORIN DAFIDI 19:1 AWỌN ọrun nsọ̀rọ ogo Ọlọrun; ati ofurufu nfi iṣẹ ọwọ rẹ̀ han. (To the chief Musician, A Psalm of David.) The heavens declare the glory of God; and the firmament sheweth his handywork.
AISAYA 43:5 Má bẹ̀ru: nitori emi wà pẹlu rẹ; emi o mu iru-ọmọ rẹ lati ìla-õrun wá, emi o si ṣà ọ jọ lati ìwọ-õrun wá. Fear not: for I am with thee: I will bring thy seed from the east, and gather thee from the west;
ORIN DAFIDI 24:9 Ẹ gbé ori nyin soke, ẹnyin ẹnu-ọ̀na; ani ki ẹ gbé wọn soke, ẹnyin ilẹkun aiyeraiye: ki Ọba ogo ki o wọ̀ inu ile wa. Lift up your heads, O ye gates; even lift them up, ye everlasting doors; and the King of glory shall come in.
ORIN DAFIDI 91:1 ẸNITI o joko ni ibi ìkọkọ Ọga-ogo ni yio ma gbe abẹ ojiji Olodumare. He that dwelleth in the secret place of the most High shall abide under the shadow of the Almighty.
ORIN DAFIDI 21:3 Nitori iwọ ti fi ibukún ore kò o li ọ̀na, iwọ fi ade kiki wura de e li ori. For thou preventest him with the blessings of goodness: thou settest a crown of pure gold on his head.
AISAYA 41:10 Fear thou not; for I am with thee: be not dismayed; for I am thy God: I will strengthen thee; yea, I will help thee; yea, I will uphold thee with the right hand of my righteousness.
HABAKUKU 3:19 The LORD God is my strength, and he will make my feet like hinds' feet, and he will make me to walk upon mine high places. To the chief singer on my stringed instruments.
ORIN DAFIDI 118:24 Eyi li ọjọ ti Oluwa da: awa o ma yọ̀, inu wa yio si ma dùn ninu rẹ̀. This is the day which the LORD hath made; we will rejoice and be glad in it.